1 Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má sì ṣe ohun tí ó wu ara wa. 2 Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró. 3 [a]Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mi.” 4 [b]Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí.
5 [c]Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin láti ní inú kan sí ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jesu Kristi, 6 kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jesu Kristi.
7 Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run. 8 Mo sì wí pé, a rán Kristi láti ṣe ìránṣẹ́ ìkọlà àwọn tí ṣe Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, 9 [d]kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
13 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.
17 Nítorí náà, mo ní ìṣògo nínú Kristi Jesu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run. 18 [i]Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi, 19 [j]nípa agbára iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìyìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 20 [k]Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìyìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn. 21 [l]Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
30 Èmí rọ̀ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nítorí Olúwa wa Jesu Kristi, àti nítorí ìfẹ́ Ẹ̀mí, kí ẹ̀yin kí ó kún mi láti bá mi làkàkà nínú àdúrà yín sí Ọlọ́run fún mi. 31 [u]Kí a lè kó mi yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Judea àti kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo ní sí Jerusalẹmu le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀, 32 [v]kí èmi le fi ayọ̀ tọ̀ yín wa, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti kí èmi lè ní ìtura pọ̀ pẹ̀lú yín. 33 [w]Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.
- a Sm 69.9.
- b Ro 4.23-24; 1Kọ 9.10; 2Tm 3.16.
- c Ro 12.16; 1Kọ 1.10; 2Kọ 13.11; Fp 2.2; 4.2.
- d Sm 18.49; 2Sa 22.50.
- e De 32.43.
- f Sm 117.1.
- g Isa 11.10; Mt 12.21.
- h Ap 9.15.
- i Ro 1.5; Ap 15.12; 21.19.
- j Ap 19.11; 2Kọ 12.12.
- k 2Kọ 10.15-16.
- l Isa 52.15.
- m Ro 1.13.
- n Ap 19.21; Ro 1.10-11; 15.32.
- o Ro 15.28.
- p Ap 19.21; 24.17; 15.31.
- q 2Kọ 8.1-5; 9.2; 1Tẹ 1.7-8.
- r 1Kọ 9.11.
- s Ro 15.24.
- t Ap 19.21.
- u 2Tẹ 3.2; Ro 15.25-26; 2Kọ 8.4; 9.1.
- v Ro 1.10; Ap 19.21.
- w 2Kọ 13.11; Fp 4.9.