Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
Saamu 88
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.
1 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
ní ọ̀sán àti ní òru, mo kígbe sókè sí Ọ.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
dẹ etí rẹ sí igbe mi.
 
3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
 
6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
7 Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
9 ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.
 
Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí,
tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?
 
13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;
ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
 
15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
èmi múra àti kú;
nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
èmi di gbére-gbère.
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò.
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
wọ́n mù mí pátápátá.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.

<- Saamu 87Saamu 89 ->