Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
Saamu 76
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.
1 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun.
Sela.
 
4 Ìwọ ni ògo àti ọlá,
ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
 
7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́,
9 nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà.
Sela.
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
 
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.

<- Saamu 75Saamu 77 ->