Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
Saamu 71
1 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
2 Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
3 Jẹ́ àpáta ààbò mi,
níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
4 Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.
 
5 Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
6 Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
7 Mo di àmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
8 Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.
 
9 Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi,
má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́.
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.
 
14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.
 
15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
Olúwa Olódùmarè;
èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.
 
19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá.
Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.
 
22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
èmi, ẹni tí o rà padà.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

<- Saamu 70Saamu 72 ->