Saamu 68
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.
1 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
kí ó fẹ́ wọn lọ;
bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.
4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
rẹ̀ mímọ́
6 Ọlọ́run gbé aláìlera
kalẹ̀ nínú ìdílé,
ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
tí ń kọjá lọ láàrín aginjù,
Sela.
8 Ilẹ̀ mì títí,
àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
níwájú Ọlọ́run,
ẹni Sinai,
níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,
púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;
obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13 Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,
nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,
àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
14 Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,
ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.
15 Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;
òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
16 Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,
ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba
níbi tí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run
ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga
ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;
ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:
nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,
kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.
19 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù.
Sela.
20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
22 Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;
èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
23 kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,
àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”
24 Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,
ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.
25 Àwọn akọrin wà ní iwájú, àwọn olórin wà lẹ́yìn;
àwọn ọmọbìnrin tí ń lu ṣaworo sì wà pẹ̀lú wọn.
26 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;
àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.
27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.
28 Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;
fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.
29 Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu
àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.
30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,
tí ń gbé láàrín eèsún
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù
pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù
títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:
tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká.
31 Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;
Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.
32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,
kọrin ìyìn sí Olúwa,
Sela.
33 Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,
tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.
34 Kéde agbára Ọlọ́run,
ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,
tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;
Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ.