Saamu 55
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Maskili ti Dafidi.
1 Fi etí sí àdúrà mi, Ọlọ́run,
má ṣe fi ojú pa ẹ̀bẹ̀ mi rẹ́:
2 gbọ́ mi kí o sì dá mi lóhùn.
Èrò mi ń dà mí láàmú, èmi sì ń pariwo.
3 Sí ohùn àwọn ọ̀tá ni,
nítorí igbe àwọn ènìyàn búburú;
nítorí wọ́n mú ìjìyà wá sórí mi,
wọ́n sì kẹ́gàn mi nínú ìbínú wọn.
4 Ọkàn mi wà nínú ìrora pẹ̀lú;
ẹ̀rù ikú kọjú ìjà sí mi.
5 Ìbẹ̀rù àti ìwárìrì wa sí ara mi;
ìbẹ̀rù ti bò mí mọ́lẹ̀.
6 Èmi sọ pé, “Èmi ìbá ní ìyẹ́ bí àdàbà!
Èmi ìbá fò lọ kí n sì sinmi.
7 Èmi ìbá sálọ, jìnnà réré,
kí ń sì dúró sí aginjù;
8 èmi ìbá yára lọ́ si ibùgbé mi ní ibi ààbò,
jìnnà kúrò nínú ìjì àti ẹ̀fúùfù líle.”
9 Da àwọn ẹni búburú láàmú, Olúwa, da ahọ́n wọn rú,
nítorí èmi rí ìwà agbára àti ìjà ní ìlú náà.
10 Ọ̀sán àti òru ni wọ́n fi ń rìn gbogbo odi kiri;
ìwà ìkà àti èébú wà láàrín rẹ̀.
11 Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀;
ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀.
12 Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi,
èmi yóò fi ara mọ́ ọn;
tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi,
èmi ìbá sá pamọ́ fún un.
13 Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi,
ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,
14 pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀,
bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run.
15 Kí ikú kí ó dé bá wọn,
kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú,
jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà,
nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.
16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
Olúwa yóò sì gbà mí.
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
o sì gbọ́ ohùn mi.
18 Ó rà mí padà láìléwu
kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú àní,
ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì
Sela,
nítorí tí wọn kò ní àyípadà,
tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.
20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;
ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,
ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;
ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,
ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.
22 1Pt 5.7.Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa
yóò sì mú ọ dúró;
òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi
wá sí ihò ìparun;
àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,
kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.