Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
Saamu 124
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi.
1 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,”
kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
2 ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,
nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,
3 nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè
nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,
4 nígbà náà ni omi
wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,
5 nígbà náà ni agbéraga
omi ìbá borí ọkàn wa.
 
6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n
bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.
7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;
okùn já àwa sì yọ.
8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,
tí ó dá ọ̀run òun ayé.

<- Saamu 123Saamu 125 ->