Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
Saamu 121
Orin fún ìgòkè.
1 Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì—
níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?
2 Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá,
ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé.
 
3 Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀;
ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé.
4 Kíyèsi, ẹni tí ń pa Israẹli mọ́,
kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn.
 
5 Olúwa ni olùpamọ́ rẹ;
Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
6 Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán
tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.
 
7 Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo
yóò pa ọkàn rẹ mọ́
8 Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́
láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

<- Saamu 120Saamu 122 ->