4
Ọgbọ́n ni o ga jùlọ
1 Tẹ́tí, ẹ̀yin ọmọ mi, sí ẹ̀kọ́ baba; fetísílẹ̀ kí o sì ní òye sí i.
2 Mo fún ọ ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro,
nítorí náà, má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi sílẹ̀.
3 Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,
mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi.
4 Ó kọ́ mi ó sì wí pé,
“Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,
pa òfin mi mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.
5 Gba ọgbọ́n, gba òye,
má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹsẹ̀ kúrò nínú rẹ̀.
6 Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,
fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojútó ọ.
7 Ọgbọ́n ni ó ga jù; nítorí náà gba ọgbọ́n.
Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye.
8 Gbé e ga, yóò sì gbé ọ ga
dìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.
9 Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹ
yóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”
10 Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,
ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.
11 Mo tọ́ ọ ṣọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́n
mo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.
12 Nígbà tí o rìn, ìgbésẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́
nígbà tí o bá sáré, ìwọ kì yóò kọsẹ̀.
13 Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;
tọ́jú u rẹ̀ dáradára nítorí òun ni ìyè rẹ.
14 Má ṣe gbé ẹsẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburú
tàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.
15 Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;
yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.
16 Nítorí wọn kò le sùn àyàfi tí wọ́n bá ṣe ibi,
wọn kò ní tòògbé àyàfi tí wọ́n bá gbé ẹlòmíràn ṣubú.
17 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ ìwà búburú
wọ́n sì ń mu wáìnì ìwà ìkà.
18 Ipa ọ̀nà olódodo dàbí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn
tí ń tànmọ́lẹ̀ sí i títí ọjọ́ fi kanrí
19 ṣùgbọ́n ọ̀nà ènìyàn búburú dàbí òkùnkùn biribiri;
wọn kò mọ ohun tí ó ń mú wọn kọsẹ̀.
20 Ọmọ mi, tẹ́tí sí ohun tí mo sọ;
fetísílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi.
21 Má ṣe jẹ́ kí wọ́n rá mọ́ ọ lójú
pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn rẹ,
22 nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó rí wọn
àti ìlera fún gbogbo ara ènìyàn.
23 Ju gbogbo nǹkan tókù lọ, pa ọkàn rẹ mọ́,
nítorí òun ni orísun ìyè.
24 Mú àrékérekè kúrò ní ẹnu rẹ;
sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ jìnnà réré sí ẹnu rẹ.
25 Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo iwájú,
jẹ́ kí ìwo ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán iwájú rẹ sá á.
26 [a]Kíyèsi ìrìn ẹsẹ̀ rẹ
sì rìn ní àwọn ọ̀nà tí ó dára nìkan.
27 Má ṣe yà sọ́tùn ún tàbí sósì;