Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
18
1 Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;
ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
 
2 Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye
ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.
 
3 Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé,
nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
 
4 Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn,
ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.
 
5 Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú
tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
 
6 Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀
ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
 
7 Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́,
ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.
 
8 Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn;
wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
 
9 Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀
arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
 
10 Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;
olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
 
11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;
wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
 
12 Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,
ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
 
13 Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,
èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
 
14 Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn,
ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
 
15 Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;
etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
 
16 Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn
a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.
 
17 Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre,
títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.
 
18 Ìbò dídì máa ń parí ìjà
a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
 
19 Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ,
ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.
 
20 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;
láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.
 
21 Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn,
àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.
 
22 Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,
o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.
 
23 Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,
ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
 
24 Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun,
ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.