Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
12
1 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀,
ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
 
2 Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa
ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.
 
3 A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú
ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.
 
4 Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀
ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
 
5 Èrò àwọn olódodo tọ́,
ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.
 
6 Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.
 
7 A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;
ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.
 
8 A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀
ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.
 
9 Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́
ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.
 
10 Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò,
ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni.
 
11 Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.
 
12 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà
ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.
 
13 A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.
 
14 Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere
bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.
 
15 Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
 
16 Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,
ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
 
17 Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí
ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
 
18 Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀
ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
 
19 Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé
ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
 
20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú
ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
 
21 Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
 
22 Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́
ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.
 
23 Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
 
24 Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba
ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.
 
25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
 
26 Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.
 
27 Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ
ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
 
28 Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà
ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.