5 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mose pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìran Josẹfu ń sọ tọ̀nà. 6 Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Selofehadi: wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn. 7 Kò sí ogún kan ní Israẹli tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Israẹli ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn pamọ́. 8 Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Israẹli lè ní ìpín nínú ogún baba wọn. 9 Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Israẹli gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”
10 Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose. 11 Nítorí pé a gbé Mahila, Tirsa, Hogla, Milka, àti Noa, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn. 12 Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìran Manase, ọmọ Josẹfu ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn.
- a Nu 27.7.