17 “ ‘Àti ní ọjọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọrọ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rú ẹbọ. 18 Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 19 Àti òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
20 “ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù. 21 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 22 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu.
23 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù. 24 Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà. 25 Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
26 “ ‘Àti ní ọjọ́ karùn-ún, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù. 27 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà. 28 Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
29 “ ‘Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù. 30 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 31 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
32 “ ‘Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù. 33 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 34 Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
35 Le 23.36.“ ‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpéjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan. 36 Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù. 37 Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 38 Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.
39 “ ‘Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ̀dún tí a yàn yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín.’ ”
40 Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún un.
<- Numeri 28Numeri 30 ->