1 [a]Nígbà tí Jesu wá sí Sinagọgu. Sì kíyèsi i ọkùnrin kan wà níbẹ̀, tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ. 2 [b]Àwọn kan nínú wọn sì ń wa ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu. Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ Ọ bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi. 3 Jesu wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ náà pé, “Dìde dúró ní iwájú ìjọ ènìyàn.”
4 Nígbà náà ni Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ǹjẹ́ ó bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi bóyá láti ṣe rere, tàbí láti ṣe búburú! Láti gbà ẹ̀mí là, tàbí pa á run?” Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́ láìfèsì.
5 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá. 6 [c]Lójúkan náà, àwọn Farisi jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jesu.
22 [n][o]Àwọn olùkọ́ni ní òfin sọ̀kalẹ̀ wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì wí pé, “Ó ni Beelsebulu, olórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ni ó sì fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde!”
23 Jesu pè wọ́n, ó sì fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀: “Báwo ni Èṣù ṣe lè lé èṣù jáde? 24 Bí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjọba náà yóò wó lulẹ̀. 25 Bákan náà, bí ilé kan bá sì yapa sí ara rẹ, ilé náà kí yóò le è dúró. 26 Bí Èṣù bá sì dìde sí ara rẹ̀, tí ó sì yapa, òun kí yóò le è dúró ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ yóò dé. 27 [p]Kò sí ẹni tí ó le wọ ilé ọkùnrin alágbára kan lọ, kí ó sì kó o ní ẹrù lọ, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà ní okùn, nígbà náà ni yóò lè kó ẹrù ní ilé rẹ̀. 28 [q]Lóòótọ́ ní mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a ó dáríjì àwọn ọmọ ènìyàn, àti gbogbo ọ̀rọ̀-òdì. 29 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́, kì yóò rí ìdáríjì títí ayé, ṣùgbọ́n ó wà nínú ewu ẹ̀bi àìnípẹ̀kun.”
30 Òun sọ eléyìí fún wọn, nítorí tí wọ́n sọ pé, “Nípa agbára ẹ̀mí àìmọ́ ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.”
33 Ṣùgbọ́n ó dá wọn lóhùn wí pé, “Ta ni í ṣe ìyá mi tàbí àwọn arákùnrin mi?”
34 Ó sì wò gbogbo àwọn tí ó jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀ yíká, ó sì wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi. 35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, òun ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”
<- Marku 2Marku 4 ->- a Mt 12.9-14; Lk 6.6-11.
- b Lk 11.54.
- c Mk 12.13.
- d Mt 4.24-25; 12.15-16; Lk 6.17-19.
- e Mt 11.21.
- f Mk 5.29,34; 6.56.
- g Mk 1.45.
- h Mt 5.1; Lk 6.12.
- i Mt 10.2-4; Lk 6.14-16; Ap 1.13.
- j Ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ tí o ń ja fun òmìnira àwọn Júù,
- k Mk 2.1; 7.1.
- l Mk 6.31.
- m Mk 3.31-35; Jh 10.20.
- n Mt 12.24-29; Lk 11.15-22.
- o Mt 9.34; 10.25.
- p Isa 49.24-25.
- q Mt 12.31-32; Lk 12.10.
- r Mt 12.46-50; Lk 8.19-21.