2 Àwọn Farisi kan tọ̀ ọ́ wá, láti dán an wò. Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó ha tọ̀nà fún ènìyàn láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?”
3 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni Mose pàṣẹ fún un yín?”
4 [c]Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda fún wa láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, kí a sì fi sílẹ̀.”
5 Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn, ó sì wí pé, “Nítorí líle àyà yín ni Mose fi kọ òfin yìí fun un yín. 6 [d]Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ayé ti ṣẹ̀, Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo. 7 [e]Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fi ara mọ́ aya rẹ̀. 8 Òun àti ìyàwó rẹ̀ yóò di ara kan náà. Nítorí náà, wọn kì í túnṣe méjì mọ́ bí kò ṣe ẹyọ ọ̀kan ṣoṣo. 9 Nítorí náà ohun ti Ọlọ́run bá sọ dọ̀kan, ki ẹnikẹ́ni máa ṣe yà wọ́n.”
10 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu nìkan wà nínú ilé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ohun kan náà. 11 [f]Jesu túbọ̀ ṣe àlàyé fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ tí ó bá sì fẹ́ ẹlòmíràn, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà sí obìnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé níyàwó. 12 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí obìnrin kan bá kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì fẹ́ ọkùnrin mìíràn, irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ṣe panṣágà.”
18 Jesu béèrè pé, arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere. 19 [k]Ìwọ mọ àwọn òfin bí: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ purọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.’ ”
20 Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá.”
21 [l]Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”
22 Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀.
23 Jesu wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!”
24 Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jesu tún sọ fún wọn pé, “Ẹyin ọmọ yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run. 25 Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.”
26 Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ni ó lè ní ìgbàlà?”
27 Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.”
28 [m]Nígbà náà ni Peteru kọjú sí Jesu, ó wí pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”
29 Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohunkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní nítorí mi àti nítorí ìyìnrere, 30 [n]tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun. 31 [o]Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò di ẹni ìkẹyìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú.”
36 Jesu béèrè pé, “Kí ni Ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi ó ṣe fún un yín?”
37 [t]Wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé, “Jẹ́ kí ọ̀kan nínú wa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ẹnìkejì ní ọwọ́ òsì nínú ògo rẹ!”
38 [u]Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè! Ṣe ẹ lè mu nínú ago kíkorò tí èmi ó mú tàbí a lè bamitiisi yín pẹ̀lú irú ì bamitiisi ìjìyà tí a ó fi bamitiisi mi?”
39 [v]Àwọn méjèèjì dáhùn pé, “Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀.”
41 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù gbọ́ ohun tí Jakọbu àti Johanu béèrè, wọ́n bínú. 42 [w]Nítorí ìdí èyí, Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé, àwọn ọba àti àwọn kèfèrí ń lo agbára lórí àwọn ènìyàn. 43 [x]Ṣùgbọ́n láàrín yín ko gbọdọ̀ ri bẹ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di olórí nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́. 44 Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ di aṣáájú nínú yín gbọdọ̀ ṣe ìránṣẹ́ gbogbo yín. 45 [y]Nítorí, Èmi, Ọmọ Ènìyàn kò wá sí ayé kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún mi, ṣùgbọ́n láti lè ṣe ìránṣẹ́ fun àwọn ẹlòmíràn, àti láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.” 46 [z]Wọ́n dé Jeriko, bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fẹ́ kúrò ní ìlú Jeriko, ọkùnrin afọ́jú kan, Bartimeu, ọmọ Timeu jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ó ń ṣagbe.
48 Àwọn tó wà níbẹ̀ kígbe mọ́ ọn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́.” Ṣùgbọ́n dípò kí ó pa ẹnu mọ́, ṣe ló ń kígbe lóhùn rara pé, “Jesu ọmọ Dafidi ṣàánú fún mi.”
49 Nígbà tí Jesu gbọ́ igbe rẹ̀, ó dẹ́sẹ̀ dúró lójú ọ̀nà, ó sì wí pé, “Ẹ pè é kí ó wá sọ́dọ̀ mi.”
51 Jesu béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ìwọ fẹ́ kí èmi kí ó ṣe fún ọ?”
52 [bb]Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọkùnrin afọ́jú náà ríran ó sì ń tẹ̀lé Jesu lọ ní ọ̀nà.
<- Marku 9Marku 11 ->- a Mt 19.1-9.
- b Lk 9.51; Jh 10.40; 11.7.
- c De 24.1-4.
- d Gẹ 1.27; 5.2.
- e Gẹ 2.24.
- f Mt 5.32; Lk 16.18; 1Kọ 7.10-11; Ro 7.2-3.
- g Mt 19.13-15; 18.3; Lk 18.15-17.
- h Mk 9.36.
- i Mt 19.16-30; Lk 18.18-30.
- j Lk 10.25; Mk 1.40.
- k Ek 20.12-16; De 5.16-20.
- l Mt 6.20; Lk 12.33; Ap 2.45; 4.34-35.
- m Mk 1.16-20.
- n Mt 6.33.
- o Mt 20.16; Lk 13.30.
- p Mt 20.17-19; Lk 18.31-34.
- q Mk 8.31; 9.12; 9.33.
- r Mk 14.65; 15.19,26-32.
- s Mt 20.20-28.
- t Mt 19.28; Lk 22.30.
- u Lk 12.50; Jh 18.11.
- v Ap 12.2; If 1.9.
- w Lk 22.25-27.
- x Mk 9.35.
- y 1Tm 2.5-6.
- z Mt 20.29-34; Lk 18.35-43; Mk 8.22-26.
- aa Mt 9.27.
- bb Mt 9.22; Mk 5.34; Lk 7.50; 8.48; 17.19.