Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
3
Bíbá àwọn olórí àti àwọn wòlíì wí
1 Nígbà náà, ni mo wí pé,
“Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jakọbu,
ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli.
Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ha ni í gba òdodo bí.
2 Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi;
ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn
àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;
3 àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi,
wọn sì bọ́ awọ ara wọn kúrò lára wọn.
Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́;
wọn sì gé e sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò,
bí ẹran inú agbada?”
 
4 Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa,
ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn.
Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn,
nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.

5 Báyìí ni Olúwa wí,

“Ní ti àwọn Wòlíì
tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà,
tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ,
wọn yóò kéde àlàáfíà;
ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu,
wọn yóò múra ogun sí i.
6 Nítorí náà òru yóò wá sórí yín,
tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan,
òkùnkùn yóò sì kùn fún yín,
tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀.
Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì
ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.
7 Ojú yóò sì ti àwọn wòlíì
àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú.
Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn,
nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
8 Ṣùgbọ́n ní tèmi,
èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa,
láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un,
àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.
 
9 Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu,
àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli,
tí ó kórìíra òdodo
tí ó sì yí òtítọ́ padà;
10 tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.
11 Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà
àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó.
Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé,
“Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa!
Ibi kan kì yóò bá wa.”
12 Nítorí náà, nítorí tiyín,
ni a ó ṣe ro Sioni bí oko,
Jerusalẹmu yóò sì di ebè
àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.

<- Mika 2Mika 4 ->