Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
4
Ìdánwò Jesu
1 [a]Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jesu sí ijù láti dán an wò láti ọwọ́ èṣù. 2 [b]Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á. 3 Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”

4 [c]Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”

5 [d]Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili. 6 [e]Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sá à ti kọ̀wé rẹ̀ pé,

“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí tìrẹ
wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn
kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

7 [f]Jesu sì dalóhùn, “A sá à ti kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

8 Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé àti gbogbo ògo wọn hàn án. 9 Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

10 [g]Jesu wí fún un pé, “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Nítorí a ti kọ ọ́ pé, ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.’ ”

11 [h]Nígbà náà ni èṣù fi í sílẹ̀ lọ, àwọn angẹli sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wàásù
12 [i]Nígbà tí Jesu gbọ́ wí pé a ti fi Johanu sínú túbú ó padà sí Galili. 13 [j]Ó kúrò ní Nasareti, ó sì lọ í gbé Kapernaumu, èyí tí ó wà létí Òkun Sebuluni àti Naftali. 14 Kí èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé,
15 [k]“Ìwọ Sebuluni àti ilẹ̀ Naftali
ọ̀nà tó lọ sí Òkun, ní ọ̀nà Jordani,
Galili ti àwọn kèfèrí.
16 Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùn
tí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,
àti àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikú
ni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”

17 [l]Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́
18 [m]Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n. 19 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 20 Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

21 Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. 22 Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Jesu ṣe ìwòsàn
23 [n]Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn. 24 Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Siria ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú ààrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn. 25 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili, Dekapoli, Jerusalẹmu, Judea, àti láti òkè odò Jordani sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

<- Matiu 3Matiu 5 ->