2 [b]Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀. 3 Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa, 4 nígbà náà ni ọrẹ Juda àti ti Jerusalẹmu yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì.
5 “Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
8 “Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run ni olè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí ní olè.
13 “Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ líle sí mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
14 “Ẹ̀yin ti wí pé, ‘Asán ni láti sin Ọlọ́run. Kí ni àwa jẹ ní èrè, nígbà tí àwa ti pa ìlànà rẹ mọ́, tí àwa sì ń rìn kiri bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní iwájú Olúwa àwọn ọmọ-ogun? 15 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí àwa pé agbéraga ni alábùkún fún. Ní òtítọ́ ni àwọn ti ń ṣe búburú ń gbèrú sí i, kódà àwọn ti ó dán Ọlọ́run wò ni a dá sí.’ ”
16 Nígbà náà ni àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa ń ba ara wọn sọ̀rọ̀, Olúwa sì tẹ́tí sí i, ó sì gbọ́. A sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀, fún àwọn tí o bẹ̀rù Olúwa, tiwọn sì bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ̀.
17 “Wọn yóò sì jẹ́ tèmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ni ọjọ́ náà, tí èmi ó dá; èmi yóò sì da wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí máa ń dá ọmọ rẹ̀ tí yóò sìn ín sí. 18 Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rí ìyàtọ̀, ìyàtọ̀ láàrín olódodo àti ẹni búburú, láàrín ẹni tí ń sìn Ọlọ́run, àti ẹni tí kò sìn ín.
<- Malaki 2Malaki 4 ->