9 Nígbà tí Jesu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ẹnu sì yà, ó sì yípadà sí ìjọ ènìyàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó wí pé, “Mo wí fún yín pé èmi kò rí irú ìgbàgbọ́ ńlá bí èyí nínú àwọn ènìyàn Israẹli.” 10 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ sì padà sí ilé, wọ́n bá ọmọ ọ̀dọ̀ náà tí ń ṣàìsàn, ara rẹ̀ ti dá.
14 Ó sì wá, ó sì fi ọwọ́ tọ́ pósí náà: àwọn tí ń rù ú dúró jẹ́. Ó sì wí pé, “Ọ̀dọ́mọkùnrin, mo wí fún ọ, dìde!” 15 Ẹni tí ó kú náà sì dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí i fọhùn. Ó sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
16 [e]Ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn: wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, pé, “Wòlíì ńlá dìde nínú wa,” àti pé, “Ọlọ́run sì wá bẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ wò!” 17 Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo Judea, àti gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
20 Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n wí pé, “Johanu onítẹ̀bọmi rán wa sọ́dọ̀ rẹ, pé, ‘Ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀, tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?’ ”
21 [g]Ní wákàtí náà, ó sì ṣe ìmúláradá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àìsàn, àti ààrùn, àti ẹ̀mí búburú; ó sì fi ìríran fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn afọ́jú. 22 [h]Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ, ẹ ròyìn nǹkan tí ẹ̀yin rí, tí ẹ̀yin sì gbọ́ fún Johanu: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, àti fún àwọn òtòṣì ni à ń wàásù ìyìnrere. 23 Alábùkún fún sì ni ẹnikẹ́ni tí kò kọsẹ̀ lára mi.”
24 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ìjọ ènìyàn ní ti Johanu pé, “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ sí ijù lọ wò? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mì? 25 Ṣùgbọ́n kín ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ní aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́? Wò ó, àwọn tí á wọ̀ ní aṣọ ògo, tí wọ́n sì ń jayé, ń bẹ ní ààfin ọba! 26 Ṣùgbọ́n kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò? Wòlíì? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ! 27 [i]Èyí yìí ni ẹni tí a ti kọ̀wé nítorí rẹ̀ pé:
29 [j](Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ àti àwọn agbowó òde, wọ́n dá Ọlọ́run láre, nítorí tí a fi ìtẹ̀bọmi Johanu tẹ̀ wọn bọ mi. 30 Ṣùgbọ́n àwọn Farisi àti àwọn amòfin kọ ète Ọlọ́run fún ara wọn, a kò bamitiisi wọn lọ́dọ̀ rẹ̀.)
31 Jesu sì wí pé, “Kí ni èmi ìbá fi àwọn ènìyàn ìran yìí wé? Kí ni wọ́n sì jọ? 32 Wọ́n dàbí àwọn ọmọ kékeré tí ó jókòó ní ibi ọjà, tí wọ́n sì ń kọ sí ara wọn, tí wọ́n sì ń wí pé,
39 [o]Nígbà tí Farisi tí ó pè é sì rí i, ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Ọkùnrin yìí ìbá ṣe wòlíì, ìbá mọ ẹni àti irú ẹni tí obìnrin yìí jẹ́ tí ń fi ọwọ́ kàn an, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”
40 Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Simoni, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”
41 “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbèsè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta. 42 [p]Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríjì àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, ta ni yóò fẹ́ ẹ jù?”
43 [q]Simoni dáhùn wí pé, “Mo ṣe bí ẹni tí ó dáríjì jù ni.”
44 Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Simoni pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹsẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n, omijé rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi ń nù wọ́n nù. 45 Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́sẹ̀. 46 Ìwọ kò fi òróró pa mí lórí, ṣùgbọ́n òun ti fi òróró pa mí lẹ́sẹ̀. 47 Ǹjẹ́ mo wí fún ọ, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í: nítorí tí ó ní ìfẹ́ púpọ̀: ẹni tí a sì dárí díẹ̀ jì, òun náà ni ó ní ìfẹ́ díẹ̀.”
48 [r]Ó sì wí fún un pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́!”
49 Àwọn tí ó bá a jókòó jẹun sì bẹ̀rẹ̀ sí í rò nínú ara wọn pé, “Ta ni èyí tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni pẹ̀lú?”
50 [s]Ó sì dáhùn wí fún obìnrin náà pé, “Ìgbàgbọ́ rẹ gbà ọ́ là, máa lọ ní àlàáfíà.”
<- Luku 6Luku 8 ->- a Mt 8.5-10,13; Jh 4.46-53.
- b Ap 10.2.
- c Mk 5.21-24,35-43; Jh 11.1-44; 1Ọb 17.17-24; 2Ọb 4.32-37.
- d Lk 7.19; 10.1; 11.39; 12.42; 13.15; 17.5-6; 18.6; 19.8; 22.61; 24.3.
- e Lk 7.39; 24.19; Mt 21.11; Jh 6.14.
- f Mt 11.2-19.
- g Mt 4.23; Mk 3.10.
- h Isa 29.18-19; 35.5-6; 61.1; Lk 4.18-19.
- i Ml 3.1; Mk 1.2.
- j Mt 21.32; Lk 3.12.
- k Lk 1.15.
- l Lk 5.29; 15.1-2; 7.36-50.
- m Mt 26.6-13; Mk 14.3-9; Jh 12.1-8.
- n Lk 11.37; 14.1.
- o Lk 7.16; 24.19; Mt 21.11; Jh 6.14.
- p Mt 18.25.
- q Lk 10.28.
- r Mt 9.2; Mk 2.5; Lk 5.20.
- s Mt 9.22; Mk 5.34; Lk 8.48.