7 Mt 12.34; 23.33.Nígbà náà ni ó wí fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí ó wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ìran paramọ́lẹ̀, ta ni ó kìlọ̀ fún un yín láti sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? 8 Jh 8.33,39.Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ má sì ṣe sí í wí nínú ara yín pé, ‘Àwa ní Abrahamu ní baba.’ Kí èmi kí ó wí fún un yín, Ọlọ́run lè gbé ọmọ dìde fún Abrahamu nínú òkúta wọ̀nyí. 9 Mt 7.19; Hb 6.7-8.Àti nísinsin yìí pẹ̀lú, a fi àáké lé gbòǹgbò igi náà, gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a óò ge lulẹ̀, a sì wọ jù sínú iná.”
10 Àwọn ènìyàn sì ń bi í pé, “Kí ni kí àwa kí ó ṣe?”
11 Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹni tí ó bá ní ẹ̀wù méjì, kí ó fi ọ̀kan fún ẹni tí kò ní; ẹni tí ó bá sì ní oúnjẹ, kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.”
12 Àwọn agbowó òde sì tọ̀ ọ́ wá láti ṣe ìtẹ̀bọmi lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bi í pé, “Olùkọ́, kí ni àwa ó ha ṣe?”
13 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe fi agbára gbà jù bí a ti rán yín lọ mọ́.”
14 Àwọn ọmọ-ogun sì béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Àti àwa, kí ni àwa ó ṣe?”
15 Ap 13.25; Jh 1.19-22.Bí àwọn ènìyàn sì ti ń retí, tí gbogbo wọn sì ń rò nínú ara wọn nítorí Johanu, bí òun ni Kristi tàbí òun kọ́; 16 Mt 3.11-12; Mk 1.7-8; Jh 1.26-27,33; Ap 1.5; 11.16; 19.4.Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú, Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín. 17 Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” 18 Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìyìnrere fún wọn.
19 Mt 14.3-4; Mk 6.17-18.Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe, 20 Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígbà tí ó fi Johanu sínú túbú.
23 Mt 1.1-17; Gẹ 5.3-32; 11.10-26; Ru 4.18-22; 1Ki 1.1-4,24-28; 2.1-15.Jh 8.57; Lk 1.27.Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu,
3:1 Lk 23.1; 9.7; 13.31; 23.7.
3:2 Jh 18.13; Ap 4.6; Mt 26.3; Jh 11.49.
3:3 Mt 3.1-10; Mk 1.1-5; Jh 1.6,23.
3:4 Isa 40.3-5.
3:6 Lk 2.30.
3:7 Mt 12.34; 23.33.
3:8 Jh 8.33,39.
3:9 Mt 7.19; Hb 6.7-8.
3:15 Ap 13.25; Jh 1.19-22.
3:16 Mt 3.11-12; Mk 1.7-8; Jh 1.26-27,33; Ap 1.5; 11.16; 19.4.
3:19 Mt 14.3-4; Mk 6.17-18.
3:21 Mt 3.13-17; Mk 1.9-11; Jh 1.29-34.
3:21 Lk 5.16; 6.12; 9.18,28; 11.1; Mk 1.35.
3:22 Sm 2.7; Isa 42.1; Lk 9.35; Ap 10.38; 2Pt 1.17.
3:23 Mt 1.1-17; Gẹ 5.3-32; 11.10-26; Ru 4.18-22; 1Ki 1.1-4,24-28; 2.1-15.
3:23 Jh 8.57; Lk 1.27.