10 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, kíyèsi i Olúwa dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti ọdún márùndínláàádọ́ta yìí wá, láti ìgbà tí Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose, nígbà tí Israẹli ń rìn kiri nínú aginjù, sì kíyèsi i nísinsin yìí, èmi nìyìí lónìí, ọmọ àrùndínláàdọ́rùn-ún ọdún. 11 Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mose rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsin yìí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ìgbà náà. 12 Nísinsin yìí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí Olúwa ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Anaki ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì ṣe olódi, ṣùgbọ́n bí Olúwa ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.”
13 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kalebu ọmọ Jefunne ó si fun un ní Hebroni ni ilẹ̀ ìní. 14 Bẹ́ẹ̀ ni Hebroni jẹ́ ti Kalebu ọmọ Jefunne ará Kenissiti láti ìgbà náà, nítorí tí ó tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Israẹli tọkàntọkàn. 15 (Hebroni a sì máa jẹ́ Kiriati-Arba ní ẹ̀yìn Arba, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Anaki.)