Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
2
Àdúrà Jona
1 Nígbà náà ni Jona gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá, 2 Ó sì wí pé:
“Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa,
òun sì gbọ́ ohùn mi.
Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún ìrànwọ́,
ìwọ sì gbọ́ ohùn mi.
3 Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú,
ní àárín Òkun,
ìṣàn omi sì yí mi káàkiri;
gbogbo bíbì omi àti rírú omi
rékọjá lórí mi.
4 Nígbà náà ni mo wí pé,
‘A ta mí nù kúrò níwájú rẹ;
ṣùgbọ́n síbẹ̀ èmi yóò tún
máa wo ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ.’
5 Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn;
ibú yí mi káàkiri,
a fi koríko odò wé mi lórí.
6 Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá;
ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí:
ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá,
Olúwa Ọlọ́run mi.
 
7 “Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi,
èmi rántí rẹ, Olúwa,
àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
nínú tẹmpili mímọ́ rẹ.
 
8 “Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké
kọ àánú ara wọn sílẹ̀.
9 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ.
Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́.
‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.’ ”

10 Olúwa sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jona sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.

<- Jona 1Jona 3 ->