37
Ọlọ́run kì í pọ́n ni lójú láìnídìí
1 “Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú,
ó sì kúrò ní ipò rẹ̀.
2 Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀,
àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
3 Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo,
mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
4 Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù;
ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá.
Òhun kì yóò sì dá àrá dúró,
nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
5 Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu;
ohùn ńlá ńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀.
6 Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’
àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’
7 Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀,
ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.
8 Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ,
wọn a sì wà ni ipò wọn.
9 Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá,
àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká.
10 Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni,
ibú omi á sì súnkì.
11 Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo,
a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
12 Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀,
kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun
tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
13 Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀,
tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
14 “Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí;
dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
15 Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀,
tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?
16 Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ,
iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
17 Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná,
nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
18 Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin,
tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?
19 “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;
nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.
20 A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀?
Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?
21 Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí
oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀,
ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.
22 Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá;
lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.
23 Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá;
nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.
24 Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀,