Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
14
Jobu tẹ̀síwájú nínú àròyé rẹ̀
1 “Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin,
ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
2 Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀;
ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
3 Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni?
Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
4 Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá?
Kò sí ẹnìkan!
5 Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀,
iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ,
ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
6 Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi,
títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
 
7 “Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá
ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ,
àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
8 Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀,
tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀,
9 síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi,
yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10 Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù,
àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.
Àgékúrú ọjọ́ ọmọ ènìyàn
11 “Bí omi ti í tán nínú ipa odò,
àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
12 bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́;
títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́,
wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
 
13 “Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú,
kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀,
títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá,
ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14 Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí?
Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀
fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
15 Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn;
ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi;
ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
17 A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò,
ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.
 
18 “Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán,
a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
19 Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì
mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀,
ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
20 Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ!
Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
21 Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀;
wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.
22 Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora
ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”

<- Jobu 13Jobu 15 ->