3 [b]Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì. 4 Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì. 5 Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀. 6 Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀. 7 Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n ó ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀. 8 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i, ó sì gbàgbọ́. 9 [c](Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú). 10 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.
13 [e]Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”
15 Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”
16 Jesu wí fún un pé, “Maria!”
17 [g]Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi. Ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín, àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”
18 [h]Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.
21 [j]Nítorí náà, Jesu sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.” 22 [k]Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́! 23 [l]Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dádúró, a dá wọn dúró.”
26 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.” 27 [n]Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”
28 Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”
29 [o]Jesu wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́, alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!”
30 [p]Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí. 31 [q]Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.
<- Johanu 19Johanu 21 ->