6 [c]Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. 7 Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú, láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.”
8 Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”
9 [d]Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba. Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’ 10 Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 11 [e]Ẹ gbà mí gbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, Baba sì wà nínú mi, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ gbà mí gbọ́ nítorí àwọn ẹ̀rí iṣẹ́ náà pàápàá! 12 Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, iṣẹ́ tí èmi ń ṣe ni òun yóò ṣe pẹ̀lú; iṣẹ́ tí ó tóbi ju wọ̀nyí lọ ni yóò sì ṣe; nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba. 13 [f]Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì béèrè ní orúkọ mi, òun náà ni èmi ó ṣe, kí a lè yin Baba lógo nínú Ọmọ. 14 Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.
22 Judasi (kì í ṣe Judasi Iskariotu) wí fún un pé, “Olúwa, èéha ti ṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ hàn fún àwa, tí kì yóò sì ṣe fún aráyé?”
23 [j]Jesu dáhùn ó sì wí fún un pé, “Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Baba mi yóò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀. 24 Ẹni tí kò fẹ́ràn mi ni kò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. Ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ń gbọ́ kì í ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.
25 “Nǹkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbà tí mo ń bá yín gbé. 26 Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, òun ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yóò sì rán yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín. 27 [k]Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, àlàáfíà mi ni mo fi fún yin, kì í ṣe bí ayé ti fi fún ni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.
28 “Ẹ̀yin sá ti gbọ́ bí mo ti wí fún yín pé, ‘Èmi ń lọ, èmi ó sì tọ̀ yín wá.’ Ìbá ṣe pé ẹ̀yin fẹ́ràn mi, ẹ̀yin ìbá yọ̀ nítorí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba; nítorí Baba mi tóbi jù mí lọ. 29 [l]Èmi sì ti sọ fún yín nísinsin yìí kí ó tó ṣẹ, pé nígbà tí ó bá ṣẹ, kí ẹ lè gbàgbọ́. 30 [m]Èmi kì yóò bá yín sọ̀rọ̀ púpọ̀, nítorí ọmọ-aládé ayé yí wá, kò sì ní nǹkan kan lòdì sí mi. 31 [n]Ṣùgbọ́n nítorí kí ayé lè mọ̀ pé èmi fẹ́ràn Baba; gẹ́gẹ́ bí Baba sì ti fi àṣẹ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi ń ṣe.