Link to home pageLanguagesLink to all Bible versions on this site
13
Jesu wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀
1 [a]Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.

2 [b]Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn; 3 tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run; 4 Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apá kan; nígbà tí ó sì mú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè. 5 [c]Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwokòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n.

6 Nígbà náà ni ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, òun sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ yóò ha wẹ ẹsẹ̀ mi?”

7 Jesu dá a lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Ohun tí èmi ń ṣe ni ìwọ kò mọ̀ nísinsin yìí; ṣùgbọ́n yóò yé ọ ní ìkẹyìn.”

8 [d]Peteru wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò wẹ̀ ẹsẹ̀ mi láé.”

Jesu sì dalóhùn pé, “Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi.”

9 Simoni Peteru wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.”

10 Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a ṣan ẹsẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo: ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.” 11 [e]Nítorí tí ó mọ ẹni tí yóò fi òun hàn; nítorí náà ni ó ṣe wí pé, kì í ṣe gbogbo yín ni ó mọ́.

12 Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹsẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí? 13 Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. 14 Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín. 15 [f]Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín. 16 [g]Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ. 17 [h]Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń ṣe wọ́n!

Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé ẹnìkan yóò fi òun hàn
18 [i]“Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ, èmi mọ àwọn tí mo yàn, ṣùgbọ́n kí Ìwé Mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’

19 [j]“Láti ìsinsin yìí lọ ni mo wí fún un yín kí ó tó dé, pé nígbà tí ó bá dé, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé èmi ni. 20 [k]Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, ó gbà mí; ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi.”

21 [l]Nígbà tí Jesu ti wí nǹkan wọ̀nyí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú nínú rẹ̀, ó sì jẹ́rìí, ó sì wí pé, “Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.”

22 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń wò ara wọn lójú, wọ́n ń ṣiyèméjì ti ẹni tí ó wí. 23 [m]Ǹjẹ́ ẹnìkan rọ̀gbọ̀kú sí àyà Jesu, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹni tí Jesu fẹ́ràn. 24 Nítorí náà ni Simoni Peteru ṣàpẹẹrẹ sí i, ó sì wí fún un pé, “Wí fún wa ti ẹni tí o ń sọ.”

25 Ẹni tí ó ń rọ̀gún ní àyà Jesu wí fún un pé, “Olúwa, ta ni í ṣe?”

26 [n]Nítorí náà Jesu dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. 27 Ní kété tí Judasi gba àkàrà náà ni Satani wọ inú rẹ̀ lọ.

Nítorí náà Jesu wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń ṣe nì, yára ṣe é kánkán.” 28 Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un. 29 [o]Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nítorí Judasi ni ó ni àpò, ni Jesu fi wí fún un pé, ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn tálákà. 30 [p]Nígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà àkókò náà si jẹ òru.
Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóò sẹ́ òun
31 [q]Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jesu wí pé, “Nísinsin yìí ni a yin Ọmọ Ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀. 32 Bí a bá yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀, Ọlọ́run yóò sì yìn ín lógo nínú òun tìkára rẹ̀, yóò sì yìn ín lógo nísinsin yìí.

33 [r]“Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin yóò wá mi, àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, níbi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò le wà; bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísinsin yìí.

34 [s]“Òfin tuntun kan ni mo fi fún yín, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín; gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì fẹ́ràn ọmọnìkejì yín. 35 Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin ń ṣe, nígbà tí ẹ̀yin bá ní ìfẹ́ sí ọmọ ẹnìkejì yín.”

36 [t]Simoni Peteru wí fún un pé, “Olúwa, níbo ni ìwọ ń lọ?”

Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí èmi ń lọ, ìwọ kì yóò lè tẹ̀lé mí nísinsin yìí; ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ̀ mí lẹ́yìn ní ìkẹyìn.”

37 [u]Peteru wí fún un pé, “Olúwa èéṣe tí èmi kò fi le tọ̀ ọ́ lẹ́hìn nísinsin yìí? Èmi ó fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”

38 Jesu dalóhùn wí pé, “Ìwọ ó ha fi ẹ̀mí rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́ lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, àkùkọ kì yóò kọ, kí ìwọ kí ó tó ṣẹ́ mi nígbà mẹ́ta!

<- Johanu 12Johanu 14 ->