18 “Nítòótọ́, èmi ti gbọ́ ìpohùnréré Efraimu wí pé,
‘Ìwọ ti bá mi wí gẹ́gẹ́ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́
èmi sì ti gbọ́ ìbáwí.
Rà mí padà, èmi yóò sì yípadà,
nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run mi.
19 Lẹ́yìn tí èmi ti yípadà,
mo ronúpìwàdà,
lẹ́yìn tí èmi ti wá mọ̀,
èmi lu àyà mi.
Ojú tì mí, mo sì dààmú;
nítorí èmi gba èrè ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’
20 Efraimu kì í ha í ṣe ọmọkùnrin mi dáradára
tí inú mi dùn sí bí?
Bí èmi ti ń sọ̀rọ̀ sí i tó,
síbẹ̀, èmi rántí rẹ̀.
Nítorí náà, ọkàn mi ṣe ohun kan fún un,
èmi káàánú gidigidi fún un,”
ni Olúwa wí.
21 “Gbé àmì ojú ọ̀nà dìde,
ṣe atọ́nà àmì,
kíyèsi òpópó ọ̀nà geere
ojú ọ̀nà tí ó ń gbà.
Yípadà ìwọ wúńdíá Israẹli,
padà sí àwọn ìlú rẹ.
22 Ìwọ yóò ti ṣìnà pẹ́ tó,
ìwọ aláìṣòótọ́ ọmọbìnrin;
Olúwa yóò dá ohun tuntun lórí ilẹ̀,
ọmọbìnrin kan yóò yí ọkùnrin kan ká.”
23 Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: “Nígbà tí èmi bá kó wọn dé láti ìgbèkùn; àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Juda àti ní àwọn ìlú rẹ̀ yóò tún lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí lẹ́ẹ̀kan sí i; wí pé, ‘Kí Olúwa kí ó bùkún fún ọ, ìwọ ibùgbé òdodo, ìwọ òkè ìwà mímọ́.’ 24 Àwọn ènìyàn yóò gbé papọ̀ ní Juda àti ní gbogbo àwọn ìlú rẹ̀; bákan náà ni àgbẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀lé agbo ẹran wọn ká. 25 Èmi yóò sọ aláàárẹ̀ di ọ̀tun, èmi yóò sì tẹ́ gbogbo ọkàn tí ń káàánú lọ́rùn.”
26 Lórí èyí ni mo jí, mo sì wò yíká, oorun mi sì dùn mọ́ mi.
27 “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Israẹli àti ilé Juda pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko. 28 Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí. 29 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé:
“ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà àìpọ́n
àti pé eyín kan àwọn ọmọdé.’
30 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èso kíkan ni eyín yóò kan.
tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’
nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí
láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,”
ni Olúwa wí.
“Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì,
èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”
35 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
ẹni tí ó mú oòrùn
tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,
tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀
ràn ní òru;
tí ó rú omi Òkun sókè
tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
36 “Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,”
ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kun
láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.”
37 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè
tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀,
ni èmi yóò kọ àwọn Israẹli
nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,”
ni Olúwa wí.
38 “Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé igun ẹnu ibodè. 39 Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Garebu yóò sì lọ sí Goa. 40 Gbogbo àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo àfonífojì Kidironi ní ìhà ìlà-oòrùn títí dé igun ẹnu ibodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa. A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀.”