7 “ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀. 8 Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀. 9 Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’
10 “Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ. 11 Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́. 12 Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti. 13 Ap 7.42.Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
14 Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé, 15 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”
<- Jeremiah 18Jeremiah 20 ->19:13 Ap 7.42.