1 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani. 2 (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun). 3 Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati. 4 A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose.
5 Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi. 6 Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.
15 Ṣùgbọ́n nígbà tí Israẹli tún ké pe Olúwa, Olúwa rán olùgbàlà kan sí wọn, Ehudu ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gera ti ẹ̀yà Benjamini. Àwọn ọmọ Israẹli fi ẹ̀bùn rán sí Egloni ọba Moabu. 16 Ehudu sì rọ idà kan olójú méjì, ìgbọ̀nwọ́ kan ní gígùn; òun sì sán an ní abẹ́ aṣọ rẹ̀ ní itan rẹ̀ ọ̀tún. 17 Ó sì mú ọrẹ náà wá fún Egloni ọba Moabu, Egloni ẹni tí ó sanra púpọ̀. 18 Lẹ́yìn tí Ehudu ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn. 19 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun fúnra rẹ̀ dé ibi ère fínfín tí ó wà létí Gilgali, ó padà sí Egloni, ó sì wí pé, “Ọba, mo ní ọ̀rọ̀ àṣírí láti bá ọ sọ.”
20 Ehudu lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Ehudu sì wí fún un pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀, 21 Ehudu fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀. 22 Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Ehudu kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà. 23 Ehudu ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.
24 Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ìlẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.” 25 Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyanu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.
26 Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Ehudu ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Seira. 27 Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó fọn ìpè ní orí òkè Efraimu, àwọn ọmọ Israẹli sì ba sọ̀kalẹ̀ lọ láti òkè náà wá, òun sì wà níwájú wọn.
28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Moabu ọ̀tá yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jordani tí ó lọ sí ilẹ̀ Moabu, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá. 29 Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ará Moabu tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà. 30 Ní ọjọ́ náà ni Israẹli ṣẹ́gun àwọn ará Moabu, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.