gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀.
15 Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe—
orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.
16 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn. 17 Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn.
18 Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.
19 Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀. 20 Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀. 21 Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ. 22Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.
23 Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Asiria yóò lọ sí Ejibiti àti àwọn ará Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Ejibiti àti ará Asiria yóò jọ́sìn papọ̀. 24 Ní ọjọ́ náà Israẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Ejibiti àti Asiria, àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé. 25Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”