8
Israẹli yípadà kúrò ní ọnà
1 “Fi ìpè sí ẹnu rẹ!
Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa
nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú,
wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
2 Israẹli kígbe pè mí,
‘Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’
3 Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀
ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀.
4 Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi
wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀.
Wọ́n fi fàdákà àti wúrà
ṣe ère fún ara wọn,
si ìparun ara wọn.
5 Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria!
Ìbínú mi ń ru sí wọn:
yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?
6 Israẹli ni wọ́n ti wá!
Ère yìí agbẹ́gilére ló ṣe é,
àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.
7 “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́
wọ́n sì ká ìjì.
Igi ọkà kò lórí,
kò sì ní mú oúnjẹ wá.
Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà
àwọn àjèjì ni yóò jẹ.
8 A ti gbé Israẹli mì,
báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
bí ohun èlò tí kò wúlò.
9 Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri.
Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín Orílẹ̀-èdè,
Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí.
Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù
lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.
11 “Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀
gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn,
ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì.
13 Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi,
wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀,
ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.
Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Wọn yóò padà sí Ejibiti.
14 [a]Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀
Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀
Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀
ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan
sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”
<- Hosea 7Hosea 9 ->
- a Am 1.4,7,10,12,14; 2.2,5.