1 Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀. 2 Ẹni tí ó lè ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn aláìmòye, tí ó sì lé bá àwọn tí ó ti yapa kẹ́dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú. 3 Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń ṣe fún ara rẹ̀ náà. 4 Kọ sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò ṣe ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Aaroni.
5 [a]Bẹ́ẹ̀ ni Kristi pẹ̀lú kò sì ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé,
7 [c]Ní ìgbà ọjọ́ Jesu nínú ayé, ó fi ìkérora rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀. 8 Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ ìgbọ́ran nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀. 9 [d]Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ tirẹ̀, 10 [e]tí a yàn ní olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melkisedeki.