4 Bẹ́ẹ̀ ni Abramu lọ bí Olúwa ti sọ fún un. Lọti náà sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani. 5 Abramu sì mú Sarai aya rẹ̀, àti Lọti ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kójọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Harani. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n sì gúnlẹ̀ síbẹ̀.
6 Abramu sì rìn la ilẹ̀ náà já títí dé ibi igi ńlá kan tí à ń pè ni More ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani sì wà ní ilẹ̀ náà. 7 [d]Olúwa sì farahan Abramu, ó sì wí fún un pé, “Irú-ọmọ rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu tẹ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa tí ó fi ara hàn án.
8 Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà-oòrùn Beteli, ó sì pàgọ́ rẹ̀ síbẹ̀. Beteli wà ní ìwọ̀-oòrùn, Ai wà ní ìlà-oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún Olúwa, ó sì ké pe orúkọ Olúwa.
9 Nígbà náà ni Abramu tẹ̀síwájú sí ìhà gúúsù.
14 Nígbà tí Abramu dé Ejibiti, àwọn ará Ejibiti ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi. 15 Nígbà tí àwọn ìjòyè Farao sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú Farao, wọ́n sì mú un lọ sí ààfin. 16 Ó sì kẹ́ Abramu dáradára nítorí Sarai, Abramu sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú ìbákasẹ.
17 Olúwa sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn búburú sí Farao àti ilé rẹ̀, nítorí Sarai aya Abramu. 18 Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Abramu, ó sì wí fun pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Kí ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe? 19 Èéṣe tí o fi wí pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ tí èmi sì fi fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya? Nítorí náà nísinsin yìí, aya rẹ náà nìyí, mú un kí o sì máa lọ.” 20 Nígbà náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì lé e jáde ti òun ti aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.
<- Gẹnẹsisi 11Gẹnẹsisi 13 ->