Ìwé sí àwọn ará Galatia
1 Paulu, aposteli tí a rán kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ ènìyàn wá, tàbí nípa ènìyàn, ṣùgbọ́n nípa Jesu Kristi àti Ọlọ́run Baba, ẹni tí ó jí i dìde kúrò nínú òkú. 2 Àti gbogbo àwọn arákùnrin tí ó wà pẹ̀lú mi,
10 [e]Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ènìyàn ni èmi ń wá ojúrere rẹ̀ ní tàbí Ọlọ́run? Tàbí ènìyàn ni èmi ń fẹ́ láti wù bí? Bí èmi bá ń fẹ́ láti wu ènìyàn, èmi kò lè jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi.
13 [g]Nítorí ẹ̀yin ti gbúròó ìgbé ayé mi nígbà àtijọ́ nínú ìsìn àwọn Júù, bí mo tí ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rékọjá ààlà, tí mo sì lépa láti bà á jẹ́. 14 [h]Mo sì ta ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yọ nínú ìsìn àwọn Júù láàrín àwọn ìran mi, mo sì ni ìtara lọ́pọ̀lọ́pọ̀ sì òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn baba mi. 15 [i]Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wú Ọlọ́run ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ láti inú ìyá mi wá, tí ó sì pé mi nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. 16 Láti fi ọmọ rẹ̀ hàn nínú mi, kì èmi lè máa wàásù ìyìnrere rẹ̀ láàrín àwọn aláìkọlà; èmi kò wá ìmọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni, 17 bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gòkè lọ sì Jerusalẹmu tọ àwọn tí í ṣe aposteli ṣáájú mi, ṣùgbọ́n mo lọ sí Arabia, mo sì tún padà wá sí Damasku.
18 [j]Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerusalẹmu láti lọ kì Peteru, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, 19 èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ aposteli, bí kò ṣe Jakọbu arákùnrin Olúwa. 20 Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí, kíyèsi i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.
21 Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Siria àti ti Kilikia. 22 Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kristi ni Judea. 23 Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsin yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.” 24 Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.
Galatia 2 ->