7 “Nítorí báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, láti ìhà àríwá ni èmi yóò ti mú Nebukadnessari ọba Babeli, ọba àwọn ọba, dìde sí Tire pẹ̀lú ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣin àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ológun. 8 Yóò sì fi idà sá àwọn ọmọbìnrin rẹ ní oko, yóò sì kọ́ odi tì ọ́, yóò sì mọ òkìtì tì ọ́, yóò sì gbé àpáta sókè sí ọ. 9 Yóò sì gbé ẹ̀rọ ogun tí odi rẹ, yóò sì fi ohun èlò ogun wó ilé ìṣọ́ rẹ palẹ̀. 10 Àwọn ẹṣin rẹ̀ yóò pọ̀ dé bí pé wọn yóò fi eruku bò ọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn ògiri rẹ yóò mì tìtì fún igbe àwọn ẹṣin ogun kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kẹ̀kẹ́ ogun nígbà tí ó bá wọ ẹnu-ọ̀nà odi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń wọ ìlú láti inú àwọn ògiri rẹ̀ ti ó di fífọ́ pátápátá. 11 Pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin rẹ̀ ni yóò fi tẹ gbogbo òpópónà rẹ mọ́lẹ̀; yóò fi idà pa àwọn ènìyàn rẹ, àwọn ọ̀wọ́n rẹ ti o lágbára yóò wó palẹ̀. 12 Wọn yóò kó ọrọ̀ rẹ, wọn yóò sì fi òwò rẹ ṣe ìjẹ ogun; wọn yóò sì wó odi rẹ lulẹ̀, wọn yóò sì ba àwọn ilé rẹ dídára jẹ́, wọn yóò sì kó àwọn òkúta rẹ̀, àti igi ìtì ìkọ́lé rẹ̀, àti erùpẹ̀ rẹ̀, dà sí inú Òkun. 13 [b]Èmi yóò sì mú ariwo orin rẹ̀ dákẹ́ àti ìró dùùrù orin rẹ̀ ni a kì yóò gbọ́ mọ́. 14 Èmi yóò sọ ọ di àpáta lásán, ìwọ yóò sì di ibi tí a ń sá àwọ̀n ẹja sí. A kì yóò sì tún ọ mọ nítorí Èmi Olúwa ti sọ ọ̀rọ̀ ní Olúwa Olódùmarè wí.
15 “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Tire: Ǹjẹ́ àwọn erékùṣù kì yóò ha wárìrì nípa ìṣubú rẹ, nígbà tí ìkórìíra ìpalára àti rírẹ́ni lọ́run bá ń ṣẹlẹ̀ ní inú rẹ? 16 [c]Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ-aládé etí Òkun yóò sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn yóò sì pa àwọn aṣọ ìgúnwà wọn da, tì wọn yóò sì bọ́ àwọn aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ kúrò. Ẹ̀rù yóò bò wọ́n, wọn yóò sì jókòó lórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọn yóò sì máa wárìrì ní gbogbo ìgbà, ẹnu yóò sì yà wọ́n sí ọ́. 17 Nígbà náà wọn yóò gbóhùn ẹkún sókè nítorí rẹ, wọn yóò sì wí fún ọ pé:
19 “Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ahoro, gẹ́gẹ́ bi àwọn ìlú tí a kò gbé inú wọn mọ́, àti nígbà tí èmi yóò mú ibú agbami Òkun wá sí orí rẹ, omi ńlá yóò sì bò ọ́, 20 nígbà tí èmi yóò mú ọ wálẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, pẹ̀lú àwọn ènìyàn àtijọ́. Èmi yóò sì gbé ọ lọ si bi ìsàlẹ̀, ní ibi ahoro àtijọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ihò, ìwọ kì yóò sì padà gbé inú rẹ̀ mọ́, èmi yóò sì gbé ògo kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 21 Èmi yóò ṣe ọ ní ẹ̀rù, ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́. Bí a tilẹ̀ wá ọ, síbẹ̀ a kì yóò tún rí ọ mọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.”
<- Esekiẹli 25Esekiẹli 27 ->