Ìwé Oniwaasu
1
Asán ni ohun ayé
1 Ọ̀rọ̀ Oniwaasu, ọmọ Dafidi, ọba Jerusalẹmu:
2 “Asán inú asán!”
Oníwàásù náà wí pé,
“Asán inú asán!
Gbogbo rẹ̀ asán ni.”
3 Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,
lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?
4 Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,
síbẹ̀ ayé dúró títí láé.
5 Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,
ó sì sáré padà sí ibi tí ó ti yọ.
6 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúúsù,
Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,
a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.
7 Gbogbo odò ń sàn sí inú Òkun,
síbẹ̀síbẹ̀ Òkun kò kún.
Níbi tí àwọn odò ti wá,
níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí.
8 Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá,
ju èyí tí ẹnu le è sọ.
Ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn,
bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́.
9 Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn
òun ni a ó tún máa ṣe padà
kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.
10 Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé,
“Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”?
Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́,
o ti wà ṣáájú tiwa.
11 Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú
bẹ́ẹ̀ ni ìrántí kì yóò sí fún
ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀
lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn.
Asán ni ọgbọ́n ènìyàn
12 Èmi, Oniwaasu ti jẹ ọba lórí Israẹli ní Jerusalẹmu rí. 13 Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà! Ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn. 14 Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
15 Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́,
ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà.
16 Mo rò nínú ara mi, “Wò ó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóso Jerusalẹmu síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.” 17 Nígbà náà ni mo fi ara jì láti ní ìmọ̀ nípa ọgbọ́n, àti pàápàá àìgbọ́n àti òmùgọ̀, ṣùgbọ́n mo rí, wí pé èyí pẹ̀lú bí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
18 Nítorí pé ọgbọ́n púpọ̀ ìbànújẹ́ púpọ̀ ní ń mú wá,