5 Bẹ́ẹ̀ ni Mose ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ilẹ̀ Moabu, bí Olúwa ti wí. 6 Ó sì sin ín nínú àfonífojì ní ilẹ̀ Moabu, ní òdìkejì Beti-Peori, ṣùgbọ́n títí di òní yìí, kò sí ẹnìkan tí ó mọ ibi tí ibojì i rẹ̀ wà. 7 Mose jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún nígbà tí ó kú, síbẹ̀ ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù. 8 Àwọn ọmọ Israẹli sọkún un Mose ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ọgbọ̀n ọjọ́ títí di ìgbà tí ọjọ́ ẹkún àti ọ̀fọ̀ Mose parí.
9 Joṣua ọmọ Nuni kún fún ẹ̀mí ọgbọ́n nítorí Mose ti gbọ́wọ́ ọ rẹ̀ lé e lórí. Àwọn ọmọ Israẹli sì fetí sí i wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
10 [a]Láti ìgbà náà kò sì sí wòlíì tí ó dìde ní Israẹli bí i Mose, ẹni tí Olúwa mọ̀ lójúkojú, 11 tí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tí Olúwa rán an láti lọ ṣe ní Ejibiti sí Farao àti sí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀ àti sí gbogbo ilẹ̀ náà. 12 Nítorí kò sí ẹni tí ó tí ì fi gbogbo ọ̀rọ̀ agbára hàn, tàbí ṣe gbogbo ẹ̀rù ńlá tí Mose fihàn ní ojú gbogbo Israẹli.
<- Deuteronomi 33- a Nu 12.6-8.