6 Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.” 7 Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkan náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun. 8 Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹmpili lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run. 9 Gbogbo ènìyàn sì rí i, ó ń rìn, ó sì yin Ọlọ́run, 10 Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe ní ẹnu-ọ̀nà Dáradára ti tẹmpili náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.
17 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe. 18 Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà. 19 Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, 20 àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu. 21 Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀. 22 [b]Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín. 23 [c]Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’
24 “Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Samuẹli wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú. 25 [d]Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Abrahamu pé, ‘Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé.’ 26 Nígbà ti Ọlọ́run jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dìde, ó kọ́ rán an sí i yín láti bùkún fún un yín, nípa yíyí olúkúlùkù yín padà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.”
<- Ìṣe àwọn Aposteli 2Ìṣe àwọn Aposteli 4 ->