7 Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tire, àwa dé Pitolemai; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ọjọ́ kan. 8 Ní ọjọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesarea; nígbà tí á sì wọ ilé Filipi efangelisti tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. 9 Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀.
10 Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Agabu. 11 Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí, ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”
12 Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 13 Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” 14 Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!”
15 Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 16 Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kesarea bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Munasoni ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Saipurọsi, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa yóò dé sí.
20 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì wí fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ rí iye ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú àwọn Júù tí ó gbàgbọ́, gbogbo wọn ni ó sì ní ìtara fún òfin. 21 Wọ́n sì ti ròyìn rẹ̀ fún wọn pé, ìwọ ń kọ́ gbogbo àwọn Júù tí ó wà láàrín àwọn aláìkọlà pé, kí wọn kọ Mose sílẹ̀, ó ń wí fún wọn pé kí wọn má ṣe kọ àwọn ọmọ wọn ní ilà mọ́, kí wọn má sì ṣe rìn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. 22 Ǹjẹ́ èwo ni ṣíṣe? Ìjọ kò lè ṣàìmá péjọpọ̀: dájúdájú wọn yóò gbọ́ pé, ìwọ dé. 23 Ǹjẹ́ èyí tí àwa ó wí fún ọ yìí ni kí o ṣe, àwa ni ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wà lábẹ́ ẹ̀jẹ́. 24 Àwọn ni kí ìwọ mú, kí o sì ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, kí ó sì san owó láti fá irun orí wọn: gbogbo ènìyàn yóò sì mọ̀ pé, kò sì òtítọ́ kan nínú ohun tí wọ́n gbọ́ sí ọ; àti pé, ìwọ tìkára rẹ ń rìn déédé, ìwọ sì ń pa òfin Mose mọ́. 25 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn aláìkọlà tí ó gbàgbọ́, àwa tí kọ̀wé, a sì ti pinnu rẹ̀ pé, kí wọn pa ara wọn mọ́ kúrò nínú ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀jẹ̀ àti ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti àgbèrè.”
26 Nígbà náà ni Paulu mú àwọn ọkùnrin náà; ní ọjọ́ kejì ó ṣe ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú wọn, ó sì wọ inú tẹmpili lọ, láti sọ ìgbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ náà yóò pé tí a ó sì fi ọrẹ lélẹ̀ fún olúkúlùkù wọn.
30 Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdò, àwọn ènìyàn sì súré jọ wọ́n sì mú Paulu, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹmpili: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn. 31 Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerusalẹmu ti dàrú. 32 Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Paulu.
33 Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì béèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe. 34 Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun. 35 Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà ipá àwọn ènìyàn. 36 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”
39 Ṣùgbọ́n Paulu sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tarsu ìlú Kilikia, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi síbẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!”
40 Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Paulu dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́ rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu, wí pé,
<- Ìṣe àwọn Aposteli 20Ìṣe àwọn Aposteli 22 ->