2 Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì lọ kúrò lẹ́yìn Dafidi, wọ́n sì ń tọ́ Ṣeba ọmọ Bikri lẹ́yìn, ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Juda sì fi ara mọ́ ọba wọn láti odò Jordani wá títí ó fi dé Jerusalẹmu.
3 Dafidi sì wà ní ilé rẹ̀ ní Jerusalẹmu; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí í ṣe àlè rẹ̀, àwọn tí ó ti fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, Ó sì há wọn mọ́ ilé, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò sì tún wọlé tọ̀ wọ́n mọ́. A sì sé wọn mọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì wà bí opó.
6 Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Nísinsin yìí Ṣeba ọmọ Bikri yóò ṣe wá ní ibi ju ti Absalomu lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má ba à rí ìlú olódi wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.” 7 Àwọn ọmọkùnrin Joabu sì jáde tọ̀ ọ́ lọ, àti àwọn Kereti, àti àwọn Peleti, àti gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára, wọ́n sì ti Jerusalẹmu jáde lọ, láti lépa Ṣeba ọmọ Bikri.
8 Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá tí ó wà ní Gibeoni, Amasa sì ṣáájú wọn, Joabu sì di àmùrè sí agbádá rẹ̀ tí ó wọ̀, ó sì sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí, nínú àkọ̀ rẹ̀, bí ó sì ti ń lọ, ó yọ́ jáde.
9 Joabu sì bi Amasa léèrè pé, “Àlàáfíà ha kọ́ ni bí, ìwọ arákùnrin mi?” Joabu sì na ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, di Amasa ní irùngbọ̀n mú láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 10 Ṣùgbọ́n Amasa kò sì kíyèsi idà tí ń bẹ lọ́wọ́ Joabu, bẹ́ẹ̀ ni òun sì fi gún un ní ikùn, ìfun rẹ̀ sì tú dà sílẹ̀, òun kò sì tún gún un mọ́, Amasa sì kú. Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì lépa Ṣeba ọmọ Bikri.
18 Ó sì sọ̀rọ̀ wí pé, “Wọ́n ti ń wí ṣáájú pé, ‘Gba ìdáhùn rẹ ní Abeli,’ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì parí ọ̀ràn náà. 19 Èmi ni ọ̀kan nínú àwọn ẹni àlàáfíà àti olóòtítọ́ ní Israẹli, ìwọ ń wá ọ̀nà láti pa ìlú kan run tí ó jẹ́ ìyá ní Israẹli, èéṣe tí ìwọ ó fi gbé ìní Olúwa mì.”
20 Joabu sì dáhùn wí pé, “Kí a má rí i, kí a má rí i lọ́dọ̀ mi pé èmi gbé mì tàbí èmi sì parun. 21 Ọ̀ràn náà kò sì rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ọkùnrin kan láti òkè Efraimu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikri, ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí ọba, àní sí Dafidi: fi òun nìkan ṣoṣo lé wa lọ́wọ́, èmi ó sì fi ìlú sílẹ̀.”
22 Obìnrin náà sì mú ìmọ́ràn rẹ̀ tọ gbogbo àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì bẹ Ṣeba ọmọ Bikri lórí, wọ́n sì sọ ọ́ sí Joabu. Òun sì fún ìpè, wọ́n sì túká ní ìlú náà, olúkúlùkù sí àgọ́ rẹ̀. Joabu sí padà lọ sí Jerusalẹmu àti sọ́dọ̀ ọba.