7 Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá. 8 A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. 9 A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. 10 Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. 11 Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.
13 [c]Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ pé, “Èmi gbàgbọ́, nítorí náà ni èmi ṣe sọ,” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ. 14 [d]Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jesu Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jesu, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín, 15 Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́. 17 Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. 18 Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.
<- 2 Kọrinti 32 Kọrinti 5 ->