5 Ẹ máa wádìí ara yín, bí ẹ̀yin bá wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa dán ara yín wò. Tàbí ẹ̀yin fúnra yín kò mọ ara yín pé Jesu Kristi wá nínú yín? Àfi bí ẹ̀yin bá jẹ́ àwọn tí a tanù. 6 Ṣùgbọ́n mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, àwa kì í ṣe àwọn tí a tanù. 7 Ǹjẹ́ àwa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí kí àwa lè farahàn bí àwọn ti ó tayọ̀, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè máa ṣe èyí tí ó dára bí àwa tilẹ̀ dàbí àwọn tí a tanù. 8 Nítorí àwa kò lè ṣe ohun kan lòdì sí òtítọ́, bí kò ṣe fún òtítọ́. 9 Nítorí àwa ń yọ̀, nígbà ti àwa jẹ́ aláìlera, tí ẹ̀yin sì jẹ́ alágbára; èyí ni àwa sì ń gbàdúrà fún pẹ̀lú, àní pípé yín. 10 Ìdí nìyí ti mo ṣe kọ̀wé àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí èmi kò sí lọ́dọ̀ yín, pé nígbà tí mo bá dé kí èmi má ba à lo ìkanra ní lílo àṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Olúwa ti fi fún mí, láti mú ìdàgbàsókè, kì í ṣe láti fà yín ṣubú.