3 Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ẹ jẹ́ mímọ́, kí ẹ sì yàgò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè, 4 kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín kọ́ láti ṣàkóso ara rẹ̀ ní ọ̀nà mímọ́ àti pẹ̀lú ọlá, 5 kì í ṣe ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà, ẹni tí kò mọ Ọlọ́run; 6 àti pé nínú ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹnikẹ́ni nínú yín máa ṣe rẹ arákùnrin rẹ̀ jẹ nípa ohunkóhun. Olúwa yóò jẹ àwọn ènìyàn ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti ń sọ fún un yín tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. 7 Nítorí Ọlọ́run kò pè wá sínú ìwà èérí, bí kò ṣe sínú ìgbé ayé mímọ́. 8 Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó kọ òfin yìí, kì í ṣe òfin ènìyàn ni ẹni náà kọ̀, bí kò ṣe òfin Ọlọ́run ẹni tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ fún ni.
9 Ṣùgbọ́n nípa ìfẹ́ ará, a kò ní láti tún kọ̀wé sí i yín, ìdí ni pé, Ọlọ́run pàápàá ń kọ́ yín láti fẹ́ràn ara yín. 10 Nítòótọ́, ẹ ní ìfẹ́ fún àwọn arákùnrin tí ó wà káàkiri Makedonia. Síbẹ̀síbẹ̀ àwa ń bẹ̀ yín, ará, pé kí ẹ̀yin kí ó máa tẹ̀síwájú nínú rẹ̀. 11 Ẹ jẹ́ kí èyí jẹ́ ìfẹ́ ọkàn yín láti gbé jẹ́ẹ́ àti láti mọ ti ara yín àti kí olúkúlùkù kọjú sí iṣẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti wí fún yín. 12 Èyí yóò mú kí àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ gbẹ́kẹ̀lé yín àti láti bu ọlá fún yín pẹ̀lú. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò ní máa wo ojú ẹnikẹ́ni láti fún yín ni owó tí ẹ ó fi san gbèsè.
Languages