5 Nígbà náà ni, Samuẹli wí pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ sí Mispa, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ Olúwa.” 6 Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mispa, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú Olúwa. Ní ọjọ́ náà, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa.” Samuẹli sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Israẹli ní Mispa.
7 Nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé àwọn Israẹli ti péjọ ní Mispa, àwọn aláṣẹ Filistini gòkè wá láti kọlù wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Filistini. 8 Wọ́n sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini.” 9 Nígbà náà ni Samuẹli mú ọ̀dọ́-àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Ó sí ké pe Olúwa nítorí ilé Israẹli, Olúwa sì dá a lóhùn.
10 Nígbà tí Samuẹli ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Filistini súnmọ́ tòsí láti bá Israẹli ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, Olúwa sán àrá ńlá lu àwọn Filistini, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 11 Àwọn ọkùnrin Israẹli tú jáde láti Mispa. Wọ́n sì ń lépa àwọn Filistini, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Beti-Kari.
12 Samuẹli mú òkúta kan ó sì fi lélẹ̀ láàrín Mispa àti Ṣeni, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ebeneseri, wí pé, “Ibí ni Olúwa ràn wá lọ́wọ́ dé.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Filistini, wọn kò sì wá sí agbègbè àwọn ọmọ Israẹli mọ́.
15 Samuẹli tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lórí Israẹli. Ní ọjọ́ ayé e rẹ̀. 16 Láti ọdún dé ọdún, ó lọ yíká láti Beteli dé Gilgali dé Mispa, ó sì ń ṣe ìdájọ́ Israẹli ní gbogbo ibi wọ̀nyí. 17 Ṣùgbọ́n ó máa ń padà sí ilé rẹ̀ ní Rama, níbí tí ilé rẹ̀ wà, ó sì túnṣe ìdájọ́ Israẹli níbẹ̀, ó sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa.
<- 1 Samuẹli 61 Samuẹli 8 ->