4 [a]Ọba sì lọ sí Gibeoni láti rú ẹbọ, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga tí ó ṣe pàtàkì jù, Solomoni sì rú ẹgbẹ̀rún (1,000) ọrẹ ẹbọ sísun lórí pẹpẹ. 5 Ní Gibeoni, Olúwa fi ara han Solomoni lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.”
6 Solomoni sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dafidi baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀síwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́.
7 “Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi. 8 Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrín àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mọye wọn. 9 Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrín rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?”
10 Inú Olúwa sì dùn pé Solomoni béèrè nǹkan yìí. 11 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá, 12 èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ. 13 Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ. 14 Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.” 15 Solomoni jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni.
19 “Ní òru, ọmọ obìnrin yìí kú nítorí tí ó sùn lé e. 20 Nígbà náà ni ó sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó sì gbé ọmọ tèmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, nígbà tí èmi ìránṣẹ́ rẹ̀ ti sùn lọ. Ó sì tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sí àyà mi. 21 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mo sì dìde láti fi ọmú fún ọmọ mi: ó sì ti kú! Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo sì wò ó fín ní òwúrọ̀, mo sì rí i pé kì í ṣe ọmọ mi tí mo bí.”
22 Obìnrin kejì sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Èyí alààyè ni ọmọ mi, èyí òkú ni ọmọ tirẹ̀.” Èyí òkú ni tirẹ̀; èyí alààyè ni tèmi.
23 Ọba sì wí pé, “Ẹni yìí wí pé, ‘Ọmọ mi ni ó wà láààyè, ọmọ tirẹ̀ ni ó kú,’ nígbà tí ẹni èkejì náà ń wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́! Ọmọ tirẹ̀ ni ó kú, ọmọ tèmi ni ó wà láààyè.’ ”
24 Nígbà náà ni ọba wí pé, “Ẹ mú idà fún mi wá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì mú idà wá fún ọba. 25 Ọba sì pàṣẹ pé, “Ẹ gé alààyè ọmọ sí méjì, kí ẹ sì mú ìdajì fún ọ̀kan, àti ìdajì fún èkejì.”
26 Obìnrin tí ọmọ tirẹ̀ wà láààyè sì kún fún àánú fún ọmọ rẹ̀, ó sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, olúwa mi, ẹ fún un ní alààyè ọmọ! Ẹ má ṣe pa á!”
27 Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, “Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́. Ẹ má ṣe pa á: òun ni ìyá rẹ̀.”
28 Nígbà tí gbogbo Israẹli gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.
<- 1 Ọba 21 Ọba 4 ->- a 2Ki 1.3-13.