6 [d]Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.” 7 Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?
8 Ni báyìí ẹ ní ohun gbogbo tí ẹ ń fẹ́! Báyìí ẹ sì ti di ọlọ́rọ̀! Ẹ ti di ọba. Lójú yín, àwa ti di ẹni ẹ̀yìn. Ìbá dùn mọ́ mi tí ó bá jẹ́ pé lóòtítọ́ ni ẹ ti di ọba lórí ìtẹ́ yín: tí a ó sì máa jẹ ọba pẹ̀lú yín! 9 [e]Nítorí mo rò pé Ọlọ́run ń fi àwa aposteli hàn ní ìkẹyìn bí ẹni tí a dá lẹ́bi ikú bí àwọn, nítorí tí a fi wá ṣe ìran wò fún àwọn ènìyàn àti àwọn angẹli àti gbogbo ayé. 10 [f]Àwa jẹ́ aṣiwèrè nítorí Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́gbọ́n nínú Kristi! Àwa jẹ́ aláìlera, ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ alágbára! Ẹ̀yin jẹ́ ẹni àyẹ́sí, àwa jẹ ẹni ẹ̀gàn! 11 [g]Títí di wákàtí yìí ni a ń rìn kiri nínú ebi àti òǹgbẹ, a n wọ aṣọ àkísà, tí a sì ń lù wa, tí a kò sì ní ibùgbé kan. 12 [h]Tí a ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́, wọn ń gàn wa, àwa ń súre, wọn ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń forítì i. 13 Wọn ń kẹ́gàn wa, àwa ń bẹ̀bẹ̀. Títí di ìsinsin yìí ni a ti wà bí ohun ẹ̀gbin ayé, bí orí àkìtàn gbogbo ayé.
14 Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti fi dójútì yín, ṣùgbọ́n láti kìlọ̀ fún un yín bí àwọn ọmọ mi tí mo yàn fẹ́. 15 [i]Nítorí bí ẹ̀yin tilẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) olùkọ́ni nínú Kristi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò ni baba púpọ̀; nítorí nínú Kristi Jesu ni mo jẹ́ baba fún un yín nípasẹ̀ ìyìnrere. 16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ máa ṣe àfarawé mi. 17 [j]Nítorí náà ni mo ṣe rán Timotiu sí i yín, ẹni tí í ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Olúwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọ̀nà mi tí ó wà nínú Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo.
18 Mo mọ̀ pé àwọn mìíràn nínú yín tó ya onígbèéraga ènìyàn, tí wọn ń rò pé ẹ̀rù ń bà mi láti wá sọ́dọ̀ yín. 19 Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yín wá ní àìpẹ́ yìí bí Olúwa bá fẹ́; èmi yóò ṣe ìwádìí bí àwọn agbéraga yìí ṣe ń sọ̀rọ̀ àti agbára tí wọ́n ní. 20 Nítorí ìjọba Ọlọ́run kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, bí kò ṣe nínú agbára. 21 [k]Èwo ni ẹ yàn? Kí ń wá sọ́dọ̀ yín pẹ̀lú pàṣán, tàbí ni ìfẹ́, àti ẹ̀mí tútù?
<- 1 Kọrinti 31 Kọrinti 5 ->- a 1Kọ 9.17; Ro 11.25; 16.25.
- b 2Kọ 1.12.
- c Ro 2.16; 1Kọ 3.13; 2Kọ 10.18; Ro 2.29.
- d 1Kọ 1.19,31; 3.19-20; 1.12; 3.4.
- e 1Kọ 15.31; 2Kọ 11.23; Ro 8.36; Hb 10.33.
- f 1Kọ 1.18; 2Kọ 11.19; 1Kọ 3.18; 2Kọ 13.9; 1Kọ 2.3.
- g Ro 8.35; 2Kọ 11.23-27.
- h Ap 18.3; 1Pt 3.9.
- i 1Kọ 1.30; Fm 10.
- j 1Kọ 16.10; Ap 16.1; 1Kọ 7.17.
- k 2Kọ 1.23.