10 [h]Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù, nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe. 11 Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.
12 [i]Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.
13 [j]Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára. 14 Ẹ máa ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́.
15 Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́. 16 Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá. 17 Mo láyọ̀ fún wíwá Stefana àti Fortunatu àti Akaiku, nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fi kún un. 18 Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba irú àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.
20 [l]Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín.